Yoruba Hymn APA 435 - Odo Agutan Olorun
APA 435
1. Odo Agutan Olorun,
Jo we mi ninu eje Re;
Sa je kin mo ‘fe Re, ‘gbana
Irora dun, iku l’ ere.
2. Fa okan mi kuro l’aiye,
K’ o je k’ o se Tire titi;
Fi edidi Re s’ aiya mi,
Edid’ ife titi aiye.
3. A! awon wonni ti yo to,
T’ o f’ iha Re se ‘sadi won!
Nwon fi O se agbara won,
Nwon nje, nwon si nmu ninu Re.
4. O kun wa loju p’ Olorun
Fe m’awa yi lo sin’ ogo!
Pe, O so eru d’ om’ Oba,
Lati ma je faji lailai!
5. Baba, mu wa ronu jinle,
K’ a le mo ise nlanla Re;
Ma sai tu okun ahon wa,
K’ a le so ibu ife Re.
6. Jesu, Iwo l’ olori wa,
‘Wo l’ a o teri wa ba fun,
‘Wo l’ a o fi okan wa fun,
B’ a ku, b’ a wa, k’ a je Tire. Amin.
Yoruba Hymn APA 435 - Odo Agutan Olorun
This is Yoruba Anglican hymns, APA 435- Odo Agutan Olorun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals