Yoruba Hymn APA 459 - Ojo oni lo tan
APA 459
1. Ojo oni lo tan,
Oru sunmole:
Okunkun ti de na,
Ile si ti su.
2. Okunkun bo ile,
Awon ’rawo yo;
Eranko at’ eiye,
Lo si busun won.
3. Jesu f’ orun didun
F’ eni alare;
Je ki ibukun Re
Pa oju mi de.
4. Je k’ omo kekere
La ala rere;
S’ oloko t’ ewu nwu
Ni oju omi.
5. Ma toju alaisan
Ti ko r’ orun sun;
Awon ti nro ibi,
Jo da won l’ekun.
6. Ninu gbogbo oru,
Je k’ angeli Re
Ma se oluso mi,
L’ ori eni mi.
7. ’Gbat’ ile ba si mo,
Je k’ emi dide;
B’ omo ti ko l’ ese
Ni iwaju Re.
8. Ogo ni fun Baba,
Ati fun Omo,
Ati f’ Emi Mimo,
Lai ati lailai. Amin.
Yoruba Hymn APA 459 - Ojo oni lo tan
This is Yoruba Anglican hymns, APA 459- Ojo oni lo tan. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals