Yoruba Hymn APA 508 - A fe ri Jesu, ’tori ojiji wa ngun

Yoruba Hymn APA 508 - A fe ri Jesu, ’tori ojiji wa ngun

Yoruba Hymn  APA 508 - A fe ri Jesu, ’tori ojiji wa ngun

APA 508

 1. A fe ri Jesu, ’tori ojiji wa ngun,

 Ojiji igba ojo aiye wa;

 A fe ri Jesu, k’O busi gbagbo wa,

 Nigba akoko titan wa ba de.


2. A fe ri Jesu, are nmu okan wa,

 A fe ri I, are nmu ara wa;

 Igbi iyonu pupo l’ o ti nlu wa,

 Igbi mi si tun ndide to wa bo.


3. A fe ri Jesu, Apata ’pile wa,

 Li ori eyiti a duro le;

 Iye, iku, gbogbo wahala aiye,

 Ko le y’ ese wa, b’ a ba roju Re.


4. A fe ri Jesu, aiye ko l’adun mo,

 Ohun t’a nyo si ri sa l’oju wa,

 Awon ore wa gbogbo l’o ti nkoja lo,

 Ao kedun won mo, se awa n ambo.


5. A fe ri Jesu, sugbon oju nro wa,

 Nitori awon ara at’ ore;

 Ara wa pelu ko fe f’aiye sile,

 Ife wa si O ko mu ’fe yi dinku.


6. A fe ri Jesu, oju okan wa fo,

 Orun su, o si jina loju wa;

 A fe ri O, O ran okan wa leti

 Iya t’O je lati san gbese wa.


7. A fe ri Jesu, eyi l’ohun t’a fe,

 Gba t’a ba ri O, ayo nla y’o de;

 ’Wo t’O ku, t’O jinde, t’O mbebe fun wa,

 ’Gbana, ’mole y’o de, okun y’o si lo. Amin.Yoruba Hymn  APA 508 - A fe ri Jesu, ’tori ojiji wa ngun

This is Yoruba Anglican hymns, APA 508- A fe ri Jesu, ’tori ojiji wa ngun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post