Yoruba Hymn APA 563- Ewe ti Oba orun

Yoruba Hymn APA 563- Ewe ti Oba orun

 Yoruba Hymn  APA 563-  Ewe ti Oba orun

APA 563

1. Ewe ti Oba orun,

 Korin didun b’e tin lo;

 Korin ’yin Olugbala,

 Ologo n’nu ise Re.


2. A nlo sodo Olorun,

 L’ ona t’ awon baba rin;

 Nwon si nyo nisisiyi,

 Ayo won l’ awa o ri.


3. Korin, agbo kekere,

 E o simi n’ite Re;

 Ib’ a pese ’joko nyin,

 Ibe si n’ ijoba nyin.


4. Woke, omo imole,

 Ilu Sion wa lokan:

 Ibe n’ile wa titi,

 Ibe l’a o r’ Oluwa.


5. Ma sa, e duro l’ayo,

 Ni eti ile ti nyin;

 Kristi Omo Baba nwi

 Pe, laifoya k’a ma lo.


6. Jesu, a nlo l’ase Re;

 A ko ’hun gbogbo sile;

 Iwo ma j’Amona wa,

 A o si ma ba O lo. Amin.



Yoruba Hymn  APA 563-  Ewe ti Oba orun,

This is Yoruba Anglican hymns, APA 563-  Ewe ti Oba orun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post