Yoruba Hymn APA 577 - Salem t’orun, Ilu ’bukun

Yoruba Hymn APA 577 - Salem t’orun, Ilu ’bukun

 Yoruba Hymn  APA 577 - Salem t’orun, Ilu ’bukun

APA 577 

1. Salem t’orun, Ilu ’bukun,

 T’o kun fun ’fe at’ayo,

 Ti a f’okuta aye ko,

 Ni orun giga loke,

 Pel’ ogun angeli yika,

 T’o nsokale b’ iyawo.


2. Lat’ ode orun lohun

 L’o ti wo aso ogo,

 T’o ye Eniti o fe o,

 Ao sin o f’oko re;

 Gbogbo ita at’ odi re

 Je kiki oso wura.


3. Ilekun re ndan fun pearli

 Nwon wa ni sisi titi;

 Awon oloto nwo ’nu re

 Nip’ eje Olugbala,

 Awon t’o farada ’ponju

 ’Tori oruko Jesu.


4. Wahala at’ iponju nla

 L’o s’okuta re lewa,

 Jesu papa l’ Eni to won

 S’ipo ti o gbe dara,

 Ife inu Re sa ni pe,

 K’ a le s’ afin Re l’ oso.


5. Ogo at’ ola fun Baba,

 Ogo at’ ola f’ Omo,

 Ogo at’ ola fun Emi,

 Metalokan titi lai;

 At’ aiyeraiye Okanna,

 Bakanna titi aiye. Amin.


APA II.


1. Kristi n’ ipile t’o daju,

 Krist l’Ori at’ Igunle,

 Asayan at’ Iyebiye,

 O so gbogbo Ijo lu;

 Iranwo Sioni Mimo,

 Igbekele re titi.


2. Si Tempili yi l’ a npe O,

 Jo wa loni, Oluwa;

 Ni opo inurere Re,

 Gbo ebe enia Re,

 Ma da ekun ibukun Re

 Sinu ile yi titi.


3. Fun awon omo Re l’ ebun

 Ti nwon ba toro nihin,

 Ore ti nwon ba si ri gba,

 K’o ma je ti won titi;

 Nikehin ninu ogo Re,

 Kin won ma ba O joba.


4. Ogo at’ola fun Baba

 Ogo at’ola f’ Omo,

 Ogo at’ola fun Emi,

 Metalokan titi lai,

 At’ aiyeraiye, Okanna,

 Bakanna titi aiye. Amin. Yoruba Hymn  APA 577 - Salem t’orun, Ilu ’bukun

This is Yoruba Anglican hymns, APA 577-  Salem t’orun, Ilu ’bukun. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post