Yoruba Hymn APA 580 - Igbala ni, igbala ni

Yoruba Hymn APA 580 - Igbala ni, igbala ni

 Yoruba Hymn  APA 580 - Igbala ni, igbala ni

APA 580

1. Igbala ni, igbala ni

 Awa elese nfe;

 Nitori ninu buburu

 T’a se l’ awa nsegbe.


2. Ise owo wa ti a nse,

 O nwi nigbagbogbo

 Pe, igbala ko si nibe,

 Ise ko le gba ni.


3. Awa nsebo, awa nrubo,

 A nkorin, a si njo;

 Sugbon a ko ri igbala

 Ninu gbogbo wonyi.


4. Nibo ni igbala gbe wa?

 Fi han ni, fi han ni:

 B’o wa loke, bi isale,

 B’o ba mo, wi fun wa.


5. Jesu ni se Olugbala,

 Jesu l’ Oluwa wa;

 Igbala wa li owo Re;

 Fun awa elese.


6. Wa nisisiyi, wa toro,

 Ife wa ninu Re;

 Enyin ti o buru l’O npe pe;

 E wa gba igbala. Amin.Yoruba Hymn  APA 580 - Igbala ni, igbala ni

This is Yoruba Anglican hymns, APA 580-  Igbala ni, igbala ni. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post