Yoruba Hymn APA 62- Sunm’ odo wa, Emmanuel
APA 62
1. Sunm’ odo wa, Emmanuel,
Wa, ra Israeli pada,
T’ o nsofo li oko eru
Titi Jesu y’o tun pada.
E yo, e yo ! Emmanuel
Y’o wa s’ odo wa Israeli.
2. Wa, Opa alade Jesse,
K’ o gba wa l’ owo ota wa
Gba wa low’ orun apadi
Fun wa ni ’segun l’ ori ’ku,
E yo, e yo, &c.
3. Sunmo wa, ’Wo Ila-orun,
Ki bibo Re se ’tunu wa.
Tu gbogbo isudede ka
M’ ese ati egbe kuro.
E yo, e yo, &c.
4. Wa Omo ’lekun Dafidi,
’Lekun orun y’o si fun O;
Tun ona orun se fun wa,
Jo se ona osi fun wa:
E yo, e yo, &c.
5. Sunmo wa Oluwa ipa,
T’ o f’ ofin fun wnia Re
Nigbani l’ or’ oke Sinai,
’Nu eru at’ agbara nla
E yo, e yo, &c. Amin
This is Yoruba Anglican hymns, APA 62 - Sunm’ odo wa, Emmanuel. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.