Yoruba Hymn APA 106 - Olorun Oluwa aiye
APA 106
1. Olorun Oluwa aiye
’Wo t’ o ran ’rawo Re,
Lati mu awon amoye
M’ ona ibugbe Re.
2. ’Gbawo’ ni ’mole oro Re
Y’o tan yi ’lu wa ka ?
Ti aiya awon oba wa
Y’o fa si odo Re ?
3. T’ awon ijoye wa gbogbo
Yio wa juba Re;
Ti ohun ti a bi won bi
Y’o j’ asan loju won ?
4. Ile wa kun fun okunkun
Okun aiye-baiye.
Ohun inira ni fun wa,
Lati jade n’nu re.
5. Sugbon Olorun Oluwa,
Tan ’mole s’ okun wa,
K’ a le ri were ’sina wa
K’ a le ko won sile
6. ’Gbana ilu wa y’o logo
Y’o m’ ore fun O wa;
Ore t’ ise atinuwa,
At’ isi otito. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 106 - Olorun Oluwa aiye . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.