Yoruba Hymn APA 127 - Sin awon onse Re, sin won
APA 127
1. Sin awon onse Re, sin won:
’W’Oba efufu, igbi;
A de won, O da won sile;
Nwon nlo’da eru n’ide:
Wa pelu won, Wa pelu won,
Apa Re l’o le gbala.
2. Nwon f’ile at’ore sile,
Bi ase Re Oluwa;
N’ile ati loju omi,
Je Alafehinti won;
Jo pelu won: Jo pelu won:
Si ma to won lailewu.
3. ’Biti ’se won ko m’eso wa,
To dabi ’se won j’asan;
Sunmo won l’anu Re, Jesu,
Mu ireti won duro;
Ran won lowo, Ran won lowo,
K’ itara won tun soji.
4. N’nu opolopo isoro,
K’ won gbekele O jesu;
Gbat’ ise nab a si ngbile,
Ki nwon mase gberaga;
Ma fi won ’le, Ma fi won ’le,
Titi nwon o r’oju Re.
5. Nibiti nwon o f’ayo ka
Eso irugbin aiye;
Nibiti nwon o wa titi,
Lodo Olupamo won:
Pelu ’segun, Pelu ’segun,
Nwon o ma korin Jesu. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 126 - Sin awon onse Re, sin won . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.