Yoruba Hymn APA 126 - Olorun ti fi Jesu se
APA 126
1. Olorun ti fi Jesu se
Etutu fun ese;
On na l’ okan mi duro ti,
Ninu igbagbo mi.
2. Olorun si ni iyonu
Si eje Omo Re;
Omo si ti mu eje na
Wo ibi mimo lo.
3. Nibe ni eje ibuwon
Nsoro rere fun wa;
Nibe ni turari didun
Ti Alufa nla wa.
4. Angeli nwo, enu ya won;
Nwon si nteri won ba
Nitori anu Olorun
T’ o f’ eje gba ni la.
5. Emi o ma fi igbagbo
Sunmo ’bi mimo yi;
Ngo ma korin s’ Olugbala,
Ngo be k’o gb’ okan mi.
6. A ya orin mi si mimo,
Nipa eje Re na;
O si dun nipa igbagbo,
O je ’towo orun. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 126 - Olorun ti fi Jesu se . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.