Yoruba Hymn APA 191 - Oluwa mo gbo pe, Iwo

Yoruba Hymn APA 191 - Oluwa mo gbo pe, Iwo

 Yoruba Hymn  APA 191 - Oluwa mo gbo pe, Iwo

APA 191

1. Oluwa mo gbo pe, Iwo

 Nro ojo ’bukun kiri;

 Itunu fun okan are,

 Ro ojo na sori mi

 An’ emi, An’ emi,

 Ro ojo na sori mi.


2. Ma koja, Baba Olore,

 Bi ese mi tile po;

 ’Wo le fi mi sile, sugbon

 Je k’anu Re ba le mi -- An’ emi.


3. Ma koja mi, Olugbala,

 Je k’emi le ro mo O:

 Emi nwa oju rere Re,

 Pe mi mo awon t’o npe – An’ emi.


4. Ma koja mi, Emi Mimo,

 ’Wo le laju afoju:

 Eleri itoye Jesu,

 Soro ase na si mi – An’ emi.


5. Mo ti sun fonfon nin’ ese,

 Mo bi O ninu koja;

 Aiye ti de okan mi, jo

 Tu mi k’o dariji mi – An’ emi.


6. Ife Olorun ti ki ye;

 Eje Krist’ iyebiye;

 Ore-ofe alainiwon;

 Gbe gbogbo re ga n’nu mi - An’ emi.


7. Ma koja mi, dariji mi,

 Fa mi mora, Oluwa;

 ’Gba o nf’ibukun f’ elomi,

 Ma s’ ai f’ ibukun fun mi –

 An’ emi, An’emi,

 Ma s’ ai f’ ibukun fun mi. Amin.

 Yoruba Hymn  APA 191 - Oluwa mo gbo pe, Iwo

This is Yoruba Anglican hymns, APA 191 -  Oluwa mo gbo pe, Iwo . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post