Yoruba Hymn APA 253 - Jerusalem ibi ayo

Yoruba Hymn APA 253 - Jerusalem ibi ayo

Yoruba Hymn  APA 253 -  Jerusalem ibi ayo

APA 253

 1. Jerusalem ibi ayo,

 T’ o se owon fun mi;

 Gbawo n’ ise mi o pari,

 L’ ayo l’ Alafia?


2. ’Gbawo ni oju mi y’o ri,

 Enu-bode pearl Re?

 Odi Re to le fun gbala,

 Ita wura didan.


3. ’Gbawo, ilu Olorun mi,

 L’ emi o d’ afin Re?

 Nibiti ijo ki ’tuka,

 Nib’ ayo ailopin.


4. Ese t’ emi o ko iya,

 Iku at’ iponju?

 Mo nwo ile rere Kenaan,

 Ile ’mole titi.


5. Apostili, martir, woli,

 Nwon y’ Olugbala ka:

 Awa tikara wa, fere

 Dapo mo ogun na.


6. Jerusalem ilu ayo,

 Okan mi nfa si o:

 Gbati mo ba ri ayo re,

 Ise mi y’o pari. Amin.


Yoruba Hymn  APA 253 -  Jerusalem ibi ayo


This is Yoruba Anglican hymns, APA 253-  Jerusalem ibi ayo   . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post