Yoruba Hymn APA 383 - Mo simi le Jesu

Yoruba Hymn APA 383 - Mo simi le Jesu

 Yoruba Hymn  APA 383 - Mo simi le Jesu

APA 383

1. Mo simi le Jesu,

 ’Wo ni mo gbekele,

 Mo kun fun ese at’ osi,

 Tani mba tun to lo?

 Li okan aiya Re nikan

 L’ okan are mi simi le.


2. Iwo Eni Mimo!

 Baba simi n’nu Re;

 Eje etutu ti O ta,

 L’o si mbebe fun mi:

 Egun tan, mo d’ alabukun:

 Mo simi ninu Baba mi.


3. Eru ese ni mi!

 ’Wo l’o da mi n’ ide;

 Okan mi si fe lati gba

 Ajaga Re s’ orun:

 Ife Re t’o gba aiya mi,

 So ’se ati lala d’ ayo.


4. Opin fere de na,

 Isimi orun mbo;

 Ese at’ irora y’o tan,

 Emi o si de ’le:

 Ngo jogun ile ileri,

 Okan mi o simi lailai. Amin. Yoruba Hymn  APA 383 - Mo simi le Jesu

This is Yoruba Anglican hymns, APA 383- Mo simi le Jesu . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post