Yoruba Hymn APA 410 - Enyin omo oku

Yoruba Hymn APA 410 - Enyin omo oku

Yoruba Hymn  APA 410 -  Enyin omo oku

APA 410

 1. Enyin omo oku,

 T’ o wa ninu ese;

 Gbohun ihinrere,

 Jesu ranse sin yin.

 Enyin eni-egbe, e wa;

 Ni apa Jesu aye mbe.


2. E ma pe titi mo,

 Ma wa awawi mo;

 O ni k’ e wa loni,

 Bi e tile ’tosi;

 Gbogbo nkan setan, elese:

 Fun gbogbo okan, aye mbe.


3. Gba oro t’ orun gbo,

 Ti onise Re nso;

 Alanu l’ Oluwa,

 Oto l’ oruko Re;

 Okan isubu, pada wa,

 S’ aigbekele nu, aye mbe.


4. Enyin t’ ife re fa,

 E sunmo odo Re;

 Kristi t’ oke pen yin,

 E gb’ ohun didun Re;

 Enikeni t’ o fe k’ o wa,

 Ni aiya anu aye mbe. Amin.



Yoruba Hymn  APA 410 -  Enyin omo oku

This is Yoruba Anglican hymns, APA 410- Enyin omo oku . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post