Yoruba Hymn APA 41 - Yin Olorun Oba wa
APA 41
1. Yin Olorun Oba wa;
Egbe ohun iyin ga;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
2. Yin Enit’o da orun
Ti o nran lojojumo;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
3. Ati osupa loru
Ti o ntanmole jeje;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
4. Yin Enit’ o nm’ojo ro
T’ o nmu irugbin dagba;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
5. Enit’ o pase fun ’le
Lati mu eso po si;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
6. Yin fun ikore oko,
O mu ki aka wa kun;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
7. Yin f’onje t’ o ju yi lo,
Eri ’bukun ailopin;
Anu Re o wa titi
Lododo dajudaju.
8. Ogo f’ Oba olore:
Ki gbogbo eda gberin:
Ogo fun Baba, Omo,
At’ Emi: Metalokan. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 41 - Yin Olorun Oba wa. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.