Yoruba Hymn APA 40 - Iwo t’ o nmu okan mole
APA 40
1. Iwo t’ o nmu okan mole,
Nipa ’mole atorunwa.
T’o sin se iri ibukun
Sor’ awon ti nsaferi Re.
2. Jo masai fi ibukun Re,
Fun oluko at’akeko;
Ki ijo Re le je mimo,
K’ atupa re ma jog ere.
3. F’okan mimo fun oluko,
Igbagbo, ’reti, at’ ife;
Ki nwon j’eniti’ Iwo ti ko
Ki nwon le j’oluko rere.
4. F’eti igboran f’akeko,
Okan ’rele at’ ailetan;
Talaka to kun f’ebun yi
San ju oba aiye yi lo.
5. Buk’ oluso; buk’ agutan,
Ki nwon j’okan labe ’so Re;
Ki nwon ma f’okan kan sona
Tit’aiye osi yi y’o pin.
6. Baba, b’awa ba n’ore Re,
Laiye yi l’a ti l’ogo;
K’a to koja s’ oke orun
L’ ao mo ohun ti aiku je. Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 40 - Iwo t’ o nmu okan mole. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.