Yoruba Hymn APA 125 - Ma sise lo, mase sare
APA 125
1. Ma sise lo, mase sare,
Fi ayo sise Baba re;
Bayi ni Jesu se l’ aiye,
Ko ha ye, k’ awa ko se be ?
2. Ma sise lo, lojojumo,
Okunkun aiye fere de;
Mura si ’se, mase s’ ole,
Ko ba le gba okan re la.
3. Pupo pupo l’ awon t’ o ku,
Ti nwon ko n’ ireti orun;
Gbe ina ’gbagbo re, ma fi,
Ma fi si okunkun aiye.
4. Ma sise lo, ma yo pelu,
Lehin ise ’wo o simi;
O fere gbohun Jesu na,
Y’o ke tantan pe, “Emi de.” Amin.
This is Yoruba Anglican hymns, APA 125 - Ma sise lo, mase sare . Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwo orin mimo.
Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.