Yoruba Anglican Hymn Apa 16 - Iwo Imole okan mi

Yoruba Anglican Hymn Apa 16 - Iwo Imole okan mi

 Yoruba Hymn Apa 16 - Iwo Imole okan mi

APA 14

 1. Iwo Imole okan mi,

 Li odo Re oru ko si,

 Ki kuku aiye ma bo O,

 Kuro l’ oju iranse Re.

 

2. Nigbat’ orun ale didun

 Ba npa ipenpeju mi de,

 K’ ero mi je lati simi

 Lai laiya Olugbala mi.


3. Ba mi gbe l’ oro tit’ ale,

 Laisi Re, emi ko le wa;

 Ba mi gbe gbat’ ile ba nsu,

 Laisi Re, emi ko le ku.


4. Bi otosi omo Re kan

 Ba tapa s’oro Re loni,

 Oluwa sise ore Re,

 Ma je k’o sun ninu ese.


5. Bukun fun awon alaisan,

 Pese fun awon talaka;

 K’ orun alawe l’ ale yi,

 Dabi orun omo titun.

 

6. Sure fun wa nigbat’ a ji,

 K’ a to m’ ohun aiye yi se,

 Titi awa o de b’ ife

 T’ a o si de ijoba Re. Amin.


This is Yoruba Anglican Hymn Apa 16 - Iwo Imole okan mi. Yoruba hymns are worship hymns used in the Anglican Church for all kinds of worship and services. It is known as Iwe orin mimo.

Hymns in the Anglican Communion are translated into different languages. In the Igbo language, we have Abu or Ekpere na Abu. In the English language, it is called Ancient and Modern or Church hymnals.

Post a Comment (0)
Previous Post Next Post